Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Hébérù 11:37-39 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

37. A sọ wọ́n ni òkúta, a fi ayùn rẹ́ wọn sì méjì, a dán wọn wò a fi idà pa wọn: wọn rìn kákiri nínú àwọ àgùntàn àti nínú àwọ ewúrẹ́; wọn di aláìní, olupọ́njú, ẹni tí a ń da lóró;

38. Àwọn ẹni tí ayé ko yẹ fún: Wọn ń kiri nínú àsálẹ̀, àti lórí òkè, àti nínú ihò àti nínú abẹ́ ilẹ̀.

39. Gbogbo àwọn wọ̀nyí tí a jẹ́ri rere sí nípa ìgbàgbọ́, wọn kò sì rí ìlérí náà gbà:

Ka pipe ipin Àwọn Hébérù 11