Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Hébérù 11:34-40 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

34. Tí wọn pa agbára iná, ti wọn bọ́ lọ́wọ́ ojú idà, tí a sọ di alágbára nínú àìlera, ti wọn dí akọni ni ìjà, wọn lé ogun àwọn àjèjì sá.

35. Àwọn obìnrin ri òkú wọn gbà nípa àjíǹde: a sì da àwọn ẹlòmíràn lóró, wọ́n kọ̀ láti gba ìdásílẹ̀; kí wọn ba lè rí àjíǹde tí o dára jù gbà;

36. Àwọn ẹlòmíràn sì rí ìjìyà ẹ̀sín, àti nínà, àti ju bẹ́ẹ̀ lọ, ti ìdè àti ti túbú:

37. A sọ wọ́n ni òkúta, a fi ayùn rẹ́ wọn sì méjì, a dán wọn wò a fi idà pa wọn: wọn rìn kákiri nínú àwọ àgùntàn àti nínú àwọ ewúrẹ́; wọn di aláìní, olupọ́njú, ẹni tí a ń da lóró;

38. Àwọn ẹni tí ayé ko yẹ fún: Wọn ń kiri nínú àsálẹ̀, àti lórí òkè, àti nínú ihò àti nínú abẹ́ ilẹ̀.

39. Gbogbo àwọn wọ̀nyí tí a jẹ́ri rere sí nípa ìgbàgbọ́, wọn kò sì rí ìlérí náà gbà:

40. Nítorí Ọlọ́run ti pèsè ohun tí o dárajù sílẹ̀ fún wa, pé láìsí wa, kí a má ṣe wọn pé.

Ka pipe ipin Àwọn Hébérù 11