Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Hébérù 1:9-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Ìwọ fẹ́ òdodo,bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kórìíra iṣẹ́ búburú;nítorí èyí ni Ọlọ́run, àní Ọlọ́run rẹ ṣe fi òróró ayọ̀ yàn ọtí ó gbé ọ ju àwọn ẹgbẹ́ rẹ lọ.”

10. Ó tún sọ pé,“Ní àtètèkọ́ṣe, ìwọ Olúwa, ìwọ fi ìdí ayé sọlẹ̀,àwọn ọ̀run sì jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ ara rẹ.

11. Wọn yóò ṣègbé, ṣùgbọ́n ìwọ yóò wà síbẹ̀gbogbo wọn ni yóò gbó di àkísà bí ẹ̀wù.

12. Ní kíká ni ìwọ yóò ká wọn bí aṣọ,bí ìpàrọ̀ aṣọ ni a ó sì pàárọ̀ wọn.Ṣùgbọ́n ìwọ fúnrarẹ kì yóò yípadààti pé ọdún rẹ kì yóò ní òpin.”

13. Èwo nínú àwọn ańgẹ́lì ní a gbọ́ pé Ọlọ́run fi ìgbà kan wí fún pé,“Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mitítí èmi yóò fi sọ àwọn ọ̀ta rẹdi àpótí ìtìsẹ̀ rẹ”?

14. Kì í ha á ṣe ẹ̀mí tí ń jísẹ́ ni àwọn ańgẹ́lì í ṣe bí; tí a rán lọ síta láti máa sisẹ́ fún àwọn tí yóò jogún ìgbàlà?

Ka pipe ipin Àwọn Hébérù 1