Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

3 Jòhánù 1:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Alàgbà,Sì Gáyúsì, olùfẹ́, ẹni tí mo fẹ́ nínú òtítọ́.

2. Olùfẹ́, èmi ń gbàdúrà pé nínú ohun gbogbo kí o lè máa dára fún ọ, kí o sì máa wà ni ìlera, àní bí o tí dára fún ọkàn rẹ.

3. Nítorí mo yọ̀ gidigidi, nígbà tí àwọn arákùnrin dé tí wọn sì jẹ̀rìí sí ìwà òtítọ́ inú rẹ̀, àní bí ìwọ tí ń rìn nínú òtítọ́.

4. Èmi ni ayọ̀ tí ó ó tayọ, láti máa gbọ́ pé, àwọn ọmọ mi ń rìn nínú ọ̀títọ́.

5. Olùfẹ́, ìwọ ń ṣe olóòótọ́ nínú iṣẹ́ tí ìwọ ń ṣe fún àwọn tí ń ṣe ará, àti pàápàá fún àwọn tí ń ṣe àlejò.

6. Tí wọn ń jẹ̀rìí sí ìfẹ́ rẹ̀ níwájú ìjọ: bí ìwọ bá ń pèsè fún wọ́n ní ọ̀nà àjò wọn gẹ́gẹ́ bí o tí yẹ nínú Ọlọ́run.

7. Nítorí pé nítorí iṣẹ́ Kírísítì ni wọ́n ṣe jáde lọ, láìgbà ohunkóhun lọ́wọ́ àwọn aláìkọlà.

8. Nítorí náà, ó yẹ kí àwa fi inú rere gba irú àwọn wọ̀nyí, kí àwa lè jẹ́ alábáṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú òtítọ́.

9. Èmi kọ̀wé sí ìjọ: ṣùgbọ́n Díótíréfè, ẹni tí ó fẹ́ láti jẹ́ ẹni pàtàkì jùlọ, kò gbà wá.

Ka pipe ipin 3 Jòhánù 1