Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Tímótíù 2:8-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Rántí Jésù Kírísítì, ti ó jíǹde kúrò nínú òkú, láti inú irú-ọmọ Dáfídì gẹ́gẹ́ bí ìyìn rere mi.

9. Nínú èyí tí èmi ń rí ìpọ́njú títí dé inú ìdè bí arúfin; ṣùgbọ́n a kò de ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

10. Nítorí náà mo ń faradà ohun gbogbo nítorí àwọn àyànfẹ́; kí àwọn náà pẹ̀lú lè ní ìgbàlà tí ń bẹ nínú Kírísítì Jésù pẹ̀lú ògo ayérayé.

11. Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ náà:Bi àwa bá bá a kú,àwa yóò yè pẹ̀lú rẹ̀.

12. Bí àwa bá faradà,àwa ó sì bá a jọba:Bí àwa bá sẹ́ ẹ,òun náà yóò sì sẹ́ wa.

13. Bí àwa kò bá gbàgbọ́,òun dúró ni olóòótọ́:Nítorí òun kò lè sẹ ara rẹ̀.

14. Nǹkan wọ̀nyí ni ki ó máa rán wọn létí. Máa kìlọ̀ò fún wọn níwajú Olúwa pé, ki wọn ó yẹra kúrò nínú jíjiyàn ọ̀rọ̀ tí kò léèrè, bí kò ṣe ìparun fún àwọn tí ń gbọ́.

15. Ṣaápọn láti fi ara rẹ̀ hàn níwájú Ọlọ́run bi ẹni tí ó yege àti òṣìṣẹ́ tí kò níláti tijú, tí ó ń pin ọ̀rọ̀ òtítọ́ bí ó ti yẹ

16. Yà kúrò nínú ọ̀rọ̀ asán, nítorí ti wọn máa ṣíwájú nínú àìwà-bí-Ọlọ́run.

17. Ọ̀rọ̀ wọn yóò sì máa fẹ́ bí egbò kíkẹ̀; nínú àwọn ẹni tí Híménéù àti Fílétù wà;

18. Àwọn ẹni tí ó ti sìnà kúrò nínú òtítọ́, tí ń wí pé àjíǹde ti kọjá ná; tí wọ́n sì ń bi ìgbàgbọ́ àwọn mìíràn ṣubú.

Ka pipe ipin 2 Tímótíù 2