Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Pétérù 2:5-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Bí òun kò si dá ayé ìgbàanì sí, nígbà tí ó mú ìkún omi wá sórí ayé àwọn aláìwà-bí-Ọlọ́run, ṣùgbọ́n ó pa Nóà mọ́, oníwàásù òdodo, pẹ̀lú àwọn ọmọ méje mìíràn.

6. Tí ó sọ àwọn ìlú Sódómù àti Gòmórà di eérú, nígbà tí ó fi ìparun pátapáta dá wọn lẹ́bí, tí ó fi wọ́n ṣe àpẹẹrẹ fún àwọn tí yóò jẹ́ aláìwà-bí-Ọlọ́run.

7. Tí ó sì yọ Lọ́tì olóòótọ́ ènìyàn, ẹni tí ìwà ẹ̀gbin àwọn ènìyàn láìlófin bà nínú jẹ́.

8. (nítorí ọkùnrin olóòótọ́ náà bí ó ti ń gbé àárin wọn, tí ó ń rí tí ó sì ń gbọ́, lójoojúmọ́ ni ìwà búburú wọn ń bá ọkàn òtítọ́ rẹ̀ jẹ́)

9. Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, Olúwa mọ bí a tí ń yọ àwọn ẹni ìwà-bí-Ọlọ́run kúrò nínú ìdẹwò àti bí a ti ń pa àwọn aláìṣòótọ́ mo fún ọjọ́ ìdájọ́ nígbà tí wọn yóò tẹ̀síwájú nínú ìjìyà ẹ̀sẹ̀ wọn.

10. Ṣùgbọ́n páàpáà àwọn tí ó ń tọ ara lẹ́yìn nínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ èérí, tí wọ́n sì ń gan àwọn ìjòyè, àwọn ọ̀dájú àti agbéraga, wọn kò bẹ̀rù láti sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí àwọn ẹni ògo.

11. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ańgẹ́lì bí wọ́n ti pọ̀ ní agbára àti ipá tó ò ní wọn kò dá wọ́n lẹ́jọ́ ẹ̀gàn níwájú Olúwa.

12. Ṣùgbọ́n àwọn wọ̀nyí ń sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn nínú ohun tí kò yé wọn. Wọ́n dàbí ẹranko tí a kò lè tù lójú, àwọn ẹ̀dá aláròse, tí a dá láti máa mú pa, bí ẹranko ni wọ́n yóò sí sègbé pẹ̀lú.

13. Wọn yóò gba ibi padà bí ibi tí wọ́n ti ṣe. Òye ìgbafẹ́ tí wọ́n ní láti máa jẹ adùn ayé. Wọ́n jẹ́ àbàwọ́n àti àbùkù, wọ́n ń jáyé nínú ìfẹ́kùfẹ̀ẹ́ wọn nígbà tí wọ́n bá ń jẹ àṣè pẹ̀lú yín.

14. Ojú wọn kún fún panságà, wọn kò sì dẹ́kun ẹ̀sẹ̀ dídá; wọ̀n ń tan àwọn tí kò dúró ṣinṣin; wọ́n yege nínú iṣẹ́ wọ̀bìà, ẹni ègún ni wọ́n.

15. Wọ́n kọ ọ̀nà tí ó tọ́ sílẹ̀, wọ́n sì sáko lọ, wọ́n tẹ̀lé ọ̀ná Bálámù ọmọ Béórì, ẹni tó fẹ́ràn èrè àìsòdodo.

16. Ṣùgbọ́n a bá a wí nítorí àṣìse rẹ̀, ẹranko tí ó kò le sọ̀rọ̀, ẹni tí ó fi ohùn ènìyàn sọ̀rọ̀ tí ó sì fi òpin sí ìsíwèrè wòlíì náà.

Ka pipe ipin 2 Pétérù 2