Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Pétérù 2:12-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Ṣùgbọ́n àwọn wọ̀nyí ń sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn nínú ohun tí kò yé wọn. Wọ́n dàbí ẹranko tí a kò lè tù lójú, àwọn ẹ̀dá aláròse, tí a dá láti máa mú pa, bí ẹranko ni wọ́n yóò sí sègbé pẹ̀lú.

13. Wọn yóò gba ibi padà bí ibi tí wọ́n ti ṣe. Òye ìgbafẹ́ tí wọ́n ní láti máa jẹ adùn ayé. Wọ́n jẹ́ àbàwọ́n àti àbùkù, wọ́n ń jáyé nínú ìfẹ́kùfẹ̀ẹ́ wọn nígbà tí wọ́n bá ń jẹ àṣè pẹ̀lú yín.

14. Ojú wọn kún fún panságà, wọn kò sì dẹ́kun ẹ̀sẹ̀ dídá; wọ̀n ń tan àwọn tí kò dúró ṣinṣin; wọ́n yege nínú iṣẹ́ wọ̀bìà, ẹni ègún ni wọ́n.

15. Wọ́n kọ ọ̀nà tí ó tọ́ sílẹ̀, wọ́n sì sáko lọ, wọ́n tẹ̀lé ọ̀ná Bálámù ọmọ Béórì, ẹni tó fẹ́ràn èrè àìsòdodo.

16. Ṣùgbọ́n a bá a wí nítorí àṣìse rẹ̀, ẹranko tí ó kò le sọ̀rọ̀, ẹni tí ó fi ohùn ènìyàn sọ̀rọ̀ tí ó sì fi òpin sí ìsíwèrè wòlíì náà.

17. Àwọn wọ̀nyí ni kànga tí kò ní omi, ìkuuku tí ẹ̀fúúfù ń gbá kiri; àwọn ẹni tí a pa òkùnkùn biribiri mọ́ dè títí láé.

18. Nítorí ìgbà tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀ ìhàlẹ̀ asán, nínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara, wọn a máa tan àwọn tí wọ́n fẹ́rẹ̀ má tí ì bọ́ tán kúrò lọ́wọ́ àwọn tí wọ́n wà nínú ìsìnà.

19. Wọn a máa ṣe ìlérí òmìnira fún wọn, nígbà tí àwọn pàápàá jẹ́ ẹrú ìdíbàjẹ́; nítorí ènìyàn tí di ẹrú ohunkóhun tí ó bá ṣe ọgá ènìyàn.

20. Lẹ́yìn tí wọ́n bá ti yọ tán kúrò nínú èérí ayé nípa mímọ́ Olúwa àti Olúgbála wá Jésù Kírísítì, bí wọn bá sì tún fi ara kó o, tí a sì ṣẹ́gun wọn, ìgbẹ̀yìn wọn a buru jú ti ìṣáájú lọ.

21. Nítorí ìbá sàn fún wọn, kí wọ́n má mọ́ ọ̀nà òdodo, jù pé lẹ́yìn tí wọ́n mọ̀ ọ́n tán, kí wọ́n yípadà kúrò nínú òfin mímọ́ tí a fi fún wọn.

22. Òwe òtítọ́ náà ṣẹ sí wọn lára: “Ajá tún padà sí èébì ara rẹ̀; àti ẹlẹ́dẹ̀ tí a ti wẹ̀ mọ́ tún padà ń yíràá nínú ẹrọ̀fọ̀.”

Ka pipe ipin 2 Pétérù 2