Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Pétérù 2:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ṣùgbọ́n àwọn wòlíì èké wà láàrin àwọn ènìyàn náà pẹ̀lú, gẹ́gẹ́ bí àwọn olùkọ́ni èké yóò ti wà láàrin yín. Wọn yóò yọ́lẹ̀ mú ẹ̀kọ́ òdì àti ègbé tọ̀ yín wa, àní tí yóò sẹ́ Olúwa tí ó rà wọ́n padà, wọ́n ó sì mú ìparun ti o yára kánkán wá sorí ara wọn.

2. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni yóò si máa tẹ̀lé ọ̀nà ìtìjú wọn, tí wọn yóò sì mú kí ọ̀nà òtítọ́ di ìsọ̀rọ̀-òdì-sí.

3. Nínù ìwà wòbìà wọn, àwọn ẹlẹ́kọ̀-òdì wọ̀nyìí yóò máa reẹ ẹ yín jẹ́ nípa ìtàn àsán. Ìdájọ́ ẹni tí kò falẹ̀ láti ìgbà yìí wá àti ìparun wọn tí kò sí tòògbé.

4. Nítorí pé bi Ọlọ́run kò bá dá àwọn ańgẹ́lì si nígbà tí wọn ṣẹ̀, ṣùgbọ́n ti ó sọ wọ́n sí ìsàlẹ̀ ọ̀gbun tí ó sì fi wọ́n sínú ọ̀gbun òkùnkùn biribiri nínú ìfipamọ́ títí dé ìdájọ́.

5. Bí òun kò si dá ayé ìgbàanì sí, nígbà tí ó mú ìkún omi wá sórí ayé àwọn aláìwà-bí-Ọlọ́run, ṣùgbọ́n ó pa Nóà mọ́, oníwàásù òdodo, pẹ̀lú àwọn ọmọ méje mìíràn.

Ka pipe ipin 2 Pétérù 2