Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kọ́ríńtì 9:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nísinsinyìí, nípa ti ìpínfúnni fún àwọn ènìyàn mímọ́, kò tún yẹ mọ́ fún mi láti kọ̀wé sí yin ju bẹ́ẹ̀ lọ.

2. Nítorí mo mọ ìmúra tẹ́lẹ̀ yín, èyí tí mo ti ṣògo fún àwọn ará Makedóníà nítorí yín, pé, Ákáyà ti múra tan níwọ̀n ọdún kan tí ó kọjá ìtara yín sì ti rú ọ̀pọ̀lọpọ̀ sókè.

3. Ṣùgbọ́n mo ti rán àwọn arákùnrin, kí ìṣògo wa nítorí yín má ṣe jásí asán ní ti ọ̀ràn yìí; pé gẹ́gẹ́ bí mó ti wí, kí ẹ̀yin lè múra tẹ́lẹ̀.

4. Kí ó má baà jẹ́ pé, bí àwọn nínú ara Makedóníà bá bá mi wá, tí wọ́n sì bá yín ní àìmúra sílẹ̀, ojú a sì tì wá kì í ṣe ẹ̀yin, ní ti ìgbẹ́kẹ̀lé yìí.

5. Nítorí náà ni mo ṣe rò pé ó yẹ láti gba àwọn arákùnrin níyànjú, kí wọn kọ́kọ́ tọ̀ yín wá, kí ẹ sì múra ẹ̀bùn yín, tí ẹ ti ṣe ìlérí tẹ́lẹ̀ sílẹ̀, kí ó lè ti wà ní lẹ̀ bí ẹ̀bùn gidi, kí ó má sì ṣe dàbí ohun ti ìfipágbà.

6. Ṣùgbọ́n èyí ni mo wí pé: Ẹni tí ó bá fúnrúgbìn kínún, kínún ni yóò ká; ẹní tí ó bá sì fúnrúgbìn púpọ̀, púpọ̀ ni yóò ká.

7. Kí olúkúlùkù ènìyàn ṣe gẹ́gẹ́ bí ó ti pinnu ní ọ̀kàn rẹ̀; kì í ṣe àfìkùnsínú ṣe, tàbí ti àìgbọ́dọ̀ má ṣe; nítorí Ọlọ́run fẹ́ onínúdídùn ọlọ́rẹ.

8. Ọlọ́run sì lè mú kí gbogbo oore ọ̀fẹ́ máa bí sí i fún yín; kí ẹ̀yin tí ó ní ànító ohun gbogbo, nígbà gbogbo, lè máa pọ̀ sí i ní iṣẹ́ rere gbogbo.

Ka pipe ipin 2 Kọ́ríńtì 9