Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kọ́ríńtì 9:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nísinsinyìí, nípa ti ìpínfúnni fún àwọn ènìyàn mímọ́, kò tún yẹ mọ́ fún mi láti kọ̀wé sí yin ju bẹ́ẹ̀ lọ.

2. Nítorí mo mọ ìmúra tẹ́lẹ̀ yín, èyí tí mo ti ṣògo fún àwọn ará Makedóníà nítorí yín, pé, Ákáyà ti múra tan níwọ̀n ọdún kan tí ó kọjá ìtara yín sì ti rú ọ̀pọ̀lọpọ̀ sókè.

3. Ṣùgbọ́n mo ti rán àwọn arákùnrin, kí ìṣògo wa nítorí yín má ṣe jásí asán ní ti ọ̀ràn yìí; pé gẹ́gẹ́ bí mó ti wí, kí ẹ̀yin lè múra tẹ́lẹ̀.

Ka pipe ipin 2 Kọ́ríńtì 9