Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kọ́ríńtì 8:9-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Nítorí ẹ̀yin mọ oore-ọ̀fẹ́ Olúwa wa Jésù Kírísítì, pé bí òun ti jẹ́ ọlọ́rọ̀ rí ṣùgbọ́n nítorí yín ó di talákà kí a lè sọ yín di ọlọ́rọ̀ nípa àìní rẹ̀.

10. Àti nínú èyí ni mo fí ìmọ̀ràn mi fún yín: nítorí èyí ṣe àǹfààní fún yín, ẹ̀yin tí ó kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ níwọ̀n ọdún tí ó kọjá, kì í ṣe láti ṣe nǹkan, ṣùgbọ́n láti fẹ́ pẹ̀lú.

11. Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ẹ parí ṣíṣe iṣẹ́ náà pẹ̀lú; kí ó baà lè ṣe pé, bí ìmúra tẹ́lẹ̀ fún ṣiṣe ti wà, bẹ́ẹ̀ ni kí ìparí sì wà láti inú agbára yín.

12. Nítorí bí ìmúra tẹ́lẹ̀ bá wà ṣáájú, ó jásí ìtẹ́wọ́gbà gẹ́gẹ́ bí ohun tí ènìyàn bá ní, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí ohun tí kò ní.

13. Nítorí èmi kò fẹ kí àwọn ẹlòmíràn wà ní ìrọ̀rùn, kí ó sì jẹ́ ìpọ́njú fún yín. Ṣùgbọ́n pé nípa mímú dọ́gba,

14. Ní àkókò yìí, pé kí àníṣẹ́kù yín lè ṣe déédé àìní wọn, kí àní ṣẹ́kù tiwọn pẹ̀lú baà lè ṣe déédé àìní yín: kí ìmúdọ́gba baà lè wà.

15. Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, “Ẹni tí o kó pọ̀ jù, kò ní nǹkan lé tayọ; ẹni tí o kò kéré jù kò ṣe aláìnító.”

16. Ṣùgbọ́n ọpẹ́ ní fún Ọlọ́run ẹni tí ó fi ìtara àníyàn kan náà yìí sí ọkàn Títù fún yín.

17. Nítorí kì í ṣe pé òun gba ọ̀rọ̀ ìyànjú wa nìkan ni; ṣùgbọ́n bí òun ti ní ìtara púpọ̀, òun tìkárarẹ̀ tọ̀ yín wá, fúnra rẹ̀.

18. Àwa ti rán arákùnrin náà pẹ̀lú rẹ̀, ìyìn ẹni tí ó wà nínú ìyìn rere yíká gbogbo ìjọ.

19. Kì í sì í ṣe bẹ́ẹ̀ nìkan, ṣùgbọ́n ẹni tí a tí yàn wá pẹ̀lú láti ọ̀dọ̀ ìjọ láti máa bá wa rìn kiri nínú ọ̀ràn oore-ọ̀fẹ́ yìí, tí àwa ń ṣe ìránṣẹ́ rẹ̀ fún ògo Olúwa àti ìmúra tẹ́lẹ̀ wa.

20. Àwa ń yẹra fún èyí, kí ẹnikẹ́ni má baà rí wí sí wa ní ti ẹ̀bùn àtinúwá yìí tí àwa pín.

21. Àwa ń gbérò ohun rere, kì í ṣe níwájú Olúwa nìkan, ṣùgbọ́n níwájú ènìyàn pẹ̀lú.

22. Àwa sì ti rán arákùnrin wa pẹ̀lú wọn, ẹni tí àwa rí dájú nígbà púpọ̀ pé ó ní ìtara nínú ohun púpọ̀, ṣùgbọ́n ní isínsnyìí ni ìtara rẹ̀ túbọ pọ̀ sí i nípa ìfọkàntàn ńlá tí ó ní sí yín.

23. Bí ẹnikẹ́ni bá béèrè ẹni tí Títù jẹ́, ẹlẹ́gbẹ́ àti olùbáṣiṣẹ́ mi ni, nítorí yín; tàbí ní ti àwọn arákùnrin wa ni ẹnikẹ́ni ń bèèrè, ìránṣẹ́ ìjọ ni wọ́n jẹ́, àti ògo Kírísítì.

24. Nítorí náà ẹ fí ẹ̀rí ìfẹ́ yín hàn wọ́n níwájú ìjọ, àti ìṣògo wa nítorí yín.

Ka pipe ipin 2 Kọ́ríńtì 8