Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kọ́ríńtì 8:22-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

22. Àwa sì ti rán arákùnrin wa pẹ̀lú wọn, ẹni tí àwa rí dájú nígbà púpọ̀ pé ó ní ìtara nínú ohun púpọ̀, ṣùgbọ́n ní isínsnyìí ni ìtara rẹ̀ túbọ pọ̀ sí i nípa ìfọkàntàn ńlá tí ó ní sí yín.

23. Bí ẹnikẹ́ni bá béèrè ẹni tí Títù jẹ́, ẹlẹ́gbẹ́ àti olùbáṣiṣẹ́ mi ni, nítorí yín; tàbí ní ti àwọn arákùnrin wa ni ẹnikẹ́ni ń bèèrè, ìránṣẹ́ ìjọ ni wọ́n jẹ́, àti ògo Kírísítì.

24. Nítorí náà ẹ fí ẹ̀rí ìfẹ́ yín hàn wọ́n níwájú ìjọ, àti ìṣògo wa nítorí yín.

Ka pipe ipin 2 Kọ́ríńtì 8