Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kọ́ríńtì 7:5-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Nítorí pé nígbà tí àwa tilẹ̀ dé Makedóníà, ara wá kò balẹ̀, ṣùgbọ́n a ń pọ́n wá lójú níhà gbogbo, ìjà ń bẹ lóde, ẹ̀rù ń bẹ nínú.

6. Ṣùgbọ́n ẹni tí ń tu àwọn onírẹ̀lẹ̀ nínú, àní Ọlọ́run, ó tù wá nínú nípa dídé tí Títù dé;

7. Kì í sì i ṣe nípa dídé rẹ̀ nìkan ṣùgbọ́n nípa ìtùnú náà pẹ̀lú tí ẹ ti tù ú nínú, nígbà tí ó ròyìn fún wa ìfẹ́ àtọkàn wá yín, ìbànújẹ́ yín, àti ìtara yín fún mi; bẹ́ẹ̀ ní mo sì túbọ̀ yọ̀.

8. Nítorí pé, bí mo tilẹ̀ ba inú yín jẹ́ nípa ìwé tí mo kọ èmi kò kábámọ̀ mọ́, bí mo tilẹ̀ ti kábámọ̀ tẹ́lẹ̀ rí; nítorí tí mo wòye pé ìwé mi mú yín banújẹ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé fún ìgbà díẹ̀.

9. Èmi yọ̀ nísinsin yìí, kì í ṣe nítorí tí a mú inú yín bàjẹ́, ṣùgbọ́n nítorí tí a mú inú yín bàjẹ́ sí ìrònúpìwàdà: nítorí ti a mú inú yín bàjẹ́ bí ẹni ìwà-bí-Ọlọ́run, kí ẹ̀yin má ṣe ti ipasẹ̀ wa pàdánù ní ohunkóhun.

Ka pipe ipin 2 Kọ́ríńtì 7