Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kọ́ríńtì 5:4-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Nítorí àwa tí ń bẹ nínú àgọ́ yìí ń kérora nítòótọ́, kì í ṣe nítorí tí àwa yóò jẹ́ aláìwọsọ, ṣùgbọ́n pé a ó wọ̀ wá ní aṣọ sí i, kí ìyè baà lè gbé ara kíkú mì.

5. Ǹjẹ́ ẹni tí ó ti pèṣè wa fún nǹkan yìí ni Ọlọ́run, ẹni tí o sì ti fi Ẹ̀mí fún wa pẹ̀lú ni ẹ̀rí ìdánilójú ohun tí ń bọ̀.

6. Nítorí náà àwa ní ìgboyà nígbà gbogbo, àwa sì mọ̀ pé, nígbà tí àwa ń bẹ ní ilé nínú ara, àwa kò sí lọ́dọ̀ Olúwa.

7. Àwa ń gbé nípa ìgbàgbọ́, kì í ṣe nípa rírí.

Ka pipe ipin 2 Kọ́ríńtì 5