Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kọ́ríńtì 5:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nítorí àwa mọ̀ pé, bi ilé àgọ́ wa ti ayé ba wó, àwa ní ilé kan láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ilé tí a kò fi ọwọ́ kọ́, ti ayérayé nínú àwọn ọ̀run.

2. Nítorí nítòótọ́ àwa ń kérora nínú èyí, àwa sì ń fẹ́ gidigidi láti fi ilé wa ti ọ̀run wọ̀ wá.

3. Bí ó bá ṣe pé a ti fi wọ̀ wá, a kì yóò bá wa ní ìhòòhò.

4. Nítorí àwa tí ń bẹ nínú àgọ́ yìí ń kérora nítòótọ́, kì í ṣe nítorí tí àwa yóò jẹ́ aláìwọsọ, ṣùgbọ́n pé a ó wọ̀ wá ní aṣọ sí i, kí ìyè baà lè gbé ara kíkú mì.

Ka pipe ipin 2 Kọ́ríńtì 5