Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kọ́ríńtì 4:8-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. A ń pọ́n wa lójú níhà gbogbo, ṣùgbọ́n ara kò ni wá: a ń dàámú wa, ṣùgbọ́n a kò sọ ìrètí nù.

9. A ń ṣe inúnibíni sí wa, ṣùgbọ́n a kò kọ̀ wá sílẹ̀; a ń rẹ̀ wá sílẹ̀ ṣùgbọ́n a kò pa wá run.

10. Nígbà gbogbo àwa ń ru ikú Jésù Olúwa kiri ni ará wa, kí a lè fi ìyè Jésù hàn pẹ̀lú lará wa.

11. Nítorí pé nígbà gbogbo ní a ń fí àwa tí ó wà láàyè fún ikú nítorí Jésù, kí a lè fi ìyè hàn nínú ara kíkú wa pẹ̀lú.

12. Bẹ́ẹ̀ ni ikú ń ṣiṣẹ́ nínú wa, ṣùgbọ́n ìyè ṣiṣẹ́ nínú yín.

13. Bí a ti kọ́, “Èmi ìgbàgbọ́, nítorí náà ni Èmi ṣe sọ.” pẹ̀lú ẹ̀mí ìgbàgbọ́ kan náà a tún gbàgbọ́ àti nítorí náà ni àwa sì ṣe ń sọ.

14. Àwa mọ̀ pé, ẹni tí o jí Jésù Olúwa dìde yóò sì jí wa dìde pẹ̀lú nípa Jésù, yóò sì mú wa wà níwájú rẹ̀ pẹ̀lú yín

15. Nítorí tiyín ní gbogbo rẹ̀, ki ọpẹ lè dí púpọ̀ fún ògo Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí oore-ọ̀fẹ́ ti ń gbòòrò sí i fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn.

16. Nítorí èyí ni àárẹ̀ kò ṣe mú wa; ṣùgbọ́n bí ọkùnrin ti òde wa bá ń parun, ṣíbẹ̀ ọkùnrin tí inú wa ń di túntún lójoojúmọ́.

17. Nítorí ìpọ́njú díẹ̀ kíún yìí ń pèsè ògo tí ó ní ìwọ̀n ayérayè tí ó pọ̀ rékọjá sílẹ̀ fún wa.

18. Níwọ̀n bí kò ti wo ohun tí a ń rí, bí kò ṣé ohun tí a kò rí; nítorí ohun tí a ń rí ni ti ìgbà ìsinsin yìí; ṣùgbọ́n ohun tí a kò rí ni ti ayérayé.

Ka pipe ipin 2 Kọ́ríńtì 4