Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kọ́ríńtì 4:1-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nitorí náà, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé nípa àánú Ọlọ́run a rí iṣẹ́ ìránṣẹ́ yìí bí àwa ti rí ní iṣẹ́-ìránṣẹ́ yìí, gẹ́gẹ́ bí a ti fi àánú gbà, àárẹ̀ kò mú wá;

2. Ṣùgbọ́n àwa tí kọ gbogbo ohun ìkọ̀kọ̀ tí ó ní ìtìjú sílẹ̀, àwa kò rìn ní ẹ̀tàn, bẹ́ẹ̀ ni àwa kò fi ọwọ́ ẹ̀tàn mú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run; ṣùgbọ́n nípa fífí òtítọ́ hàn, àwa ń fí ara wa le ẹ̀rí ọkàn olúkúlùkù ènìyàn lọ́wọ́ níwájú Ọlọ́run.

3. Ṣùgbọ́n báyìí, bí iyinrere wa bá sí farasin, ó farasin fún àwọn tí ó ń ṣègbé.

4. Nínú àwọn ẹni tí Ọlọ́run ayé yìí ti sọ ọkàn àwọn aláìgbàgbọ́ dí afọ́jú, kí ìmọ́lẹ̀ ìyìn rere Kírísítì tí ó lógo, ẹni tí í ṣe àworán Ọlọ́run, má ṣe mọ́lẹ̀ nínú wọn.

5. Nítórí àwa kò wàásù àwa tìkárawa, bí kò se Kírísítì Jésù Olúwa; àwa tikarawa sì jẹ́ ẹrú yín nítorí Jésù.

6. Nítorí Ọlọ́run ni ẹni tí ó wí pé, “Kí ìmọ́lẹ̀ ó mọ́lẹ̀ láti inú òkùnkùn jáde,” òun ní ó ti ń mọ́lẹ̀ lọ́kan wa, láti fún wa ní ìmọ́lẹ̀ ìmọ̀ ògo Ọlọ́run ní ojú Jésù Kírísítì.

7. Ṣùgbọ́n àwa ní ìṣúra yìí nínú ohun èlò àìmọ́, kí ọlá ńlá agbára náà lè jẹ́ ti Ọlọ́run, kí ó má ṣe ti ọ̀dọ̀ wa wá.

8. A ń pọ́n wa lójú níhà gbogbo, ṣùgbọ́n ara kò ni wá: a ń dàámú wa, ṣùgbọ́n a kò sọ ìrètí nù.

9. A ń ṣe inúnibíni sí wa, ṣùgbọ́n a kò kọ̀ wá sílẹ̀; a ń rẹ̀ wá sílẹ̀ ṣùgbọ́n a kò pa wá run.

10. Nígbà gbogbo àwa ń ru ikú Jésù Olúwa kiri ni ará wa, kí a lè fi ìyè Jésù hàn pẹ̀lú lará wa.

11. Nítorí pé nígbà gbogbo ní a ń fí àwa tí ó wà láàyè fún ikú nítorí Jésù, kí a lè fi ìyè hàn nínú ara kíkú wa pẹ̀lú.

12. Bẹ́ẹ̀ ni ikú ń ṣiṣẹ́ nínú wa, ṣùgbọ́n ìyè ṣiṣẹ́ nínú yín.

Ka pipe ipin 2 Kọ́ríńtì 4