Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kọ́ríńtì 3:9-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Nítorí pé bi iṣẹ́ìrànṣẹ́ ìdálẹ́bi bá jẹ́ ológo, mélòó mélòó ni iṣẹ́ ìrànṣẹ́ òdodo yóò tayọ jù ú ní ògo.

10. Nítorí, èyí tí a tí ṣe lógo rí, kó lógo mọ́ báyìí, nítorí ògo tí ó tayọ.

11. Nítorí pé bí èyí ti ń kójá lọ bá lógo, mélòó mélòó ni èyí tí ó dúró kí yóò ní ògo.?

12. Ǹjẹ́ nítorí náà bí a tí ní irú ìrètí bí èyí, àwa ń fí ìgbóyà púpọ̀ sọ̀rọ̀.

13. Kì í sì í ṣe bí Mósè, ẹni tí ó fí ìbòjú bo ojú rẹ̀, ki àwọn ọmọ Ísríẹ́lì má baà lè tẹjú mọ wíwo òpin èyí tí ń kọjá lọ

14. Ṣùgbọ́n ojú-inú wọn fọ́; nítorí pé títí fí di òní olónìí nípa kíka májẹ̀mu láéláé, ìbòjú kan náà sì wà láìká kúrò; nítorí pé nínú Kírísítì ni a tí lè mú ìbòjú náà kúrò.

15. Ṣùgbọ́n títí di òní olónìí, nígbákùúgbà ti a bá ń ka Mósè, ìbòjú náà ń bẹ lọ́kan wọn.

16. Ṣùgbọ́n nígbà ti òun bá yípadà sí Olúwa, a ó mú ìbòjú náà kúrò.

17. Ǹjẹ́ Olúwa ni Ẹ̀mí náà: níbì tí Ẹ̀mí Olúwa bá sì wà, níbẹ̀ ni òmìnirà gbé wà

18. Ṣùgbọ́n gbogbo wa ń wo ògo Olúwa láìsí ìbòjú bí ẹni pé nínú àwòjijì, a sì ń pawádà sí àwòrán kan náà láti ògo dé ògo, àní bí láti ọ̀dọ̀ Olúwa tí í ṣe Ẹ̀mí.

Ka pipe ipin 2 Kọ́ríńtì 3