Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kọ́ríńtì 3:8-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Yóò há ti rí tí iṣẹ́ ìránṣẹ́ ti ẹ̀mí kì yóò kúkú jẹ́ ògo jù?

9. Nítorí pé bi iṣẹ́ìrànṣẹ́ ìdálẹ́bi bá jẹ́ ológo, mélòó mélòó ni iṣẹ́ ìrànṣẹ́ òdodo yóò tayọ jù ú ní ògo.

10. Nítorí, èyí tí a tí ṣe lógo rí, kó lógo mọ́ báyìí, nítorí ògo tí ó tayọ.

11. Nítorí pé bí èyí ti ń kójá lọ bá lógo, mélòó mélòó ni èyí tí ó dúró kí yóò ní ògo.?

12. Ǹjẹ́ nítorí náà bí a tí ní irú ìrètí bí èyí, àwa ń fí ìgbóyà púpọ̀ sọ̀rọ̀.

13. Kì í sì í ṣe bí Mósè, ẹni tí ó fí ìbòjú bo ojú rẹ̀, ki àwọn ọmọ Ísríẹ́lì má baà lè tẹjú mọ wíwo òpin èyí tí ń kọjá lọ

14. Ṣùgbọ́n ojú-inú wọn fọ́; nítorí pé títí fí di òní olónìí nípa kíka májẹ̀mu láéláé, ìbòjú kan náà sì wà láìká kúrò; nítorí pé nínú Kírísítì ni a tí lè mú ìbòjú náà kúrò.

15. Ṣùgbọ́n títí di òní olónìí, nígbákùúgbà ti a bá ń ka Mósè, ìbòjú náà ń bẹ lọ́kan wọn.

16. Ṣùgbọ́n nígbà ti òun bá yípadà sí Olúwa, a ó mú ìbòjú náà kúrò.

Ka pipe ipin 2 Kọ́ríńtì 3