Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kọ́ríńtì 3:3-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Ẹ̀yin sì ń fi hàn pé ìwé tí a gbà sílẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Kírísítì ni yín, kì í ṣe èyí tí a si fi jẹ́lú kọ, bí kò sẹ Ẹ̀mí Ọlọ́run alààyè; kì í ṣe nínú wàláà okútà bí kò ṣe nínú wàláà ọkàn ènìyàn.

4. Irú ìgbẹ́kẹ̀lẹ́ yìí ni àwa ní nípaṣẹ̀ Kírísítì sọ́dọ̀ Ọlọ́run:

5. Kì í ṣe pé àwa tó fún ara wa láti ṣírò ohunkóhun bí ẹni pé làti ọ̀dọ̀ àwa tìkárawa; ṣùgbọ́n láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ní tító wà;

6. Ẹni tí ó mú wa tó bí ìránṣẹ́ májẹ̀mú titun; kì í ṣe ní ti ìwé-àkọọ́lẹ̀ nítorí ìwé a máa pani, ṣùgbọ́n ẹ̀mí a máa sọ ni dí ààyè.

7. Ṣùgbọ́n bí iṣẹ́ ìránṣẹ́ tí ikú, tí a tí kọ tí a sì ti gbẹ́ sí ara òkúta bá jẹ́ ológo tó bẹẹ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò lè tẹjúmọ́ wíwo ojú Mósè nítorí ògo ojú rẹ̀ (ògo ti ń kọjá lọ);

8. Yóò há ti rí tí iṣẹ́ ìránṣẹ́ ti ẹ̀mí kì yóò kúkú jẹ́ ògo jù?

9. Nítorí pé bi iṣẹ́ìrànṣẹ́ ìdálẹ́bi bá jẹ́ ológo, mélòó mélòó ni iṣẹ́ ìrànṣẹ́ òdodo yóò tayọ jù ú ní ògo.

10. Nítorí, èyí tí a tí ṣe lógo rí, kó lógo mọ́ báyìí, nítorí ògo tí ó tayọ.

11. Nítorí pé bí èyí ti ń kójá lọ bá lógo, mélòó mélòó ni èyí tí ó dúró kí yóò ní ògo.?

12. Ǹjẹ́ nítorí náà bí a tí ní irú ìrètí bí èyí, àwa ń fí ìgbóyà púpọ̀ sọ̀rọ̀.

Ka pipe ipin 2 Kọ́ríńtì 3