Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kọ́ríńtì 2:9-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Ìdí tí mo ṣe kọ̀wé, kí èmi baà lè rí ẹ̀rí dìmú nípa ìgbọ́ràn yín nínú ohun gbogbo.

10. Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá dáríjín ẹnikẹ́ni, èmí fi jì pẹ̀lú. Èmi ti dárìjìn níwájú Kírítí nítorí yín.

11. Kí Sàtánì má baà rẹ́ wa jẹ. Nítorí àwa kò ṣe aláìmọ́ àrékérekè rẹ̀.

12. Ṣùgbọ́n nígbá ti mo dé Tíróà láti wàásù iyinrere Kírísitì, tí mo sì ríi wí pé Olúwa ti sílẹ̀kùn fún mi,

13. Síbẹ̀ èmi kò ní àlàáfíà lọ́kan mi, nítorí tí èmi kò rí Títù arákùnrin mi níbẹ̀. Nítorí ìdí èyí ni mo ṣe dágbére fún wọn, mo si rékọjá lọ sí Makedóníà,

Ka pipe ipin 2 Kọ́ríńtì 2