Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kọ́ríńtì 2:15-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Nítorí òórùn dídùn Kírísítì ni àwa jẹ́ fún Ọlọ́run, nínú àwọn tí a ń gbàlà àti nínú àwọn tí ó ń ṣègbé:

16. Fún àwọn kan, àwa jẹ́ òórùn ikú sí ikú, àti fún àwọn mìíràn òórùn ìyè sí ìyè. Ta ni ó há si tọ́ fún nǹkan wọ̀nyí?

17. Nítorí àwa kò dàbí àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀, tí ń fí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣòwò jẹun; ṣùgbọ́n nínú òtítọ́ inú àwa ń sọ̀rọ̀ níwájú Ọlọ́run nínú Kírísítì gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a rán láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá.

Ka pipe ipin 2 Kọ́ríńtì 2