Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kọ́ríńtì 11:21-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

21. Èmi ń wí lọ́nà ẹ̀gàn, bí ẹni pé àwa jẹ́ aláìlera!Ṣùgbọ́n nínú ohunkóhun tí ẹnìkan ti ní ìgboyà, èmi ń sọ̀rọ̀ bí òmùgọ̀, èmi ní ìgboyà pẹ̀lú.

22. Hébérù ni wọ́n bí? Bẹ́ẹ̀ ni èmi. Ísírẹ́lì ni wọ́n bí? Bẹ́ẹ̀ ni èmi. Irú ọmọ Ábúráhámù ní òun bí? Bẹ́ẹ̀ ni èmi.

23. Iránṣẹ́ Kírísítì ni wọ́n bí? Èmi ń sọ bí òmùgọ̀, mo ta wọ́n yọ; ní ti làálàá lọ́pọ̀lọpọ̀, ní ti pàṣán, mo rékọjá, ní ti túbú nígbákùúgbà, ní ti fífẹ́rẹ̀ kú nígbà púpọ̀.

24. Nígbà márùn-ún ni mo gba pàṣán ogójì dín kan lọ́wọ́ àwọn Júù.

25. Nígbà mẹ́ta ni a fi ọ̀gọ̀ lù mí, ẹ̀ẹ̀kanṣoṣo ni a sọ mí ní òkúta, ẹ̀ẹ̀mẹ́ta ni ọkọ̀ ojú omi mi rì, ọ̀sán kan àti òru kan ni mo wà nínú ibú.

26. Ní ìrìnàjò nígbákùúgbà, nínú ewu omi, nínú ewu àwọn ọlọ́ṣà, nínú ewu àwọn ará ìlú mi, nínú ewu àwọn aláìkọlà, nínú ewu ni ìlú, nínú ewu ní ihà, nínú ewu lójú òkun, nínú ewu láàárin àwọn èké arákùnrin.

27. Nínú làálàá àti ìrora, nínú ìṣọ́-òru nígbákùúgbà, nínú ebi àti òrùgbẹ, nínú ààwẹ̀ nígbákùúgbà, nínú òtútù àti ìhòòhò.

28. Pẹ̀lú nǹkan wọ̀nyí tí ó jẹ́ tí òde, ọ̀pọ̀ ni èyí tí ń wọ́ jọ tì mí lójoojúmọ́, àní àníyàn fún gbogbo ìjọ.

29. Ta ni ó ṣe àìlera, tí èmi kò ṣe àìlera? Tàbí a mú kọsẹ̀, tí ara mi kò gbiná?

30. Bí èmi yóò bá ṣògo, èmi ó kúkú máa ṣògo nípa àwọn nǹkan tí ó jẹ́ ti àìlera mi.

31. Ọlọ́run àti Baba Olúwa wá Jésù Kírísítì, ẹni tí ó jẹ́ olùbùkún jùlọ láéláé mọ̀ pé èmi kò ṣèké.

32. Ní Dámásíkù, baálẹ̀ tí ó wà lábẹ́ ọba Árétà fí ẹgbẹ́ ogun ká ìlú àwọn ara Dámásíkù mọ́, ó ń fẹ́ mi láti mú:

Ka pipe ipin 2 Kọ́ríńtì 11