Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kọ́ríńtì 1:16-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. Mo pinnu láti bẹ̀ yín wò ní ìrìn àjò mi sí Makedóníà àti láti tún bẹ̀ yín wò nígbà tí mo bá ń padà bọ̀ láti Makedóníà àti wí pé kí ẹ̀yin kí ó lè rán mi láti ọ̀dọ̀ yín ní ìrìn àjò mi sí Jùdíà.

17. Nítorí náà nígbà tí èmi ń gbérò bẹ́ẹ̀, èmi há ṣiyèméjì bí? Tàbí àwọn ohun tí mo pinnu, mo ha pinnu wọn gẹ́gẹ́ bí ti ará bí, pé kí ó jẹ́ “Bẹ́ẹ̀ ní, bẹ́ẹ̀ ní” àti “Bẹ́ẹ̀ kọ́, bẹ́ẹ̀ kọ́”?

18. Ṣùgbọ́n bí Ọlọ́run tí jẹ́ olóòótọ́, ọ̀rọ̀ wa fún yín kí í ṣe bẹ́ẹ̀ ni ati bẹ́ẹ̀ kọ́.

19. Nítorí pé Jésù Kírísítì, Ọmọ Ọlọ́run, ẹni tí a tí wàásù rẹ̀ láàárin yín nípaṣẹ̀ èmí àti Silífánù àti Tímótíù, kì í ṣe bẹ́ẹ̀ ni bẹ́ẹ̀ kọ́, ṣùgbọ́n nínú rẹ̀ ni bẹ́ẹ̀ ní.

20. Nítorí tí gbogbo ìlérí Ọlọ́run dí bẹ́ẹ̀ ni nínú Kírísítì. Nítorí ìdí èyí ní a ṣe ń wí pé “Àmín” nípaṣẹ̀ rẹ̀ sí ògo Ọlọ́run.

21. Ǹjẹ́ níṣinṣin yìí, Ọlọ́run ni ó fí ẹsẹ̀ wa múlẹ̀ pẹ̀lú yín nínú Kírísítì, Òun ni ó ti fi àmì òróró yàn wá,

22. ó sì fí èdìdì rẹ̀ dì wá pẹ̀lú, ó sì tí fi Ẹ̀mí rẹ́ sí wa ní ọkàn gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí ìdánilójú ohun tí ó ń bọ̀.

23. Mo sì pe Ọlọ́run ṣe ẹlẹ́rìí ọkàn mi pé nítorí àtidá yín sí ní èmi kò ṣe padà sí Kọ́ríńtì.

24. Kì í ṣe nítorí tí àwa jẹ gàba lórí ìgbàgbọ́ yín: ṣùgbọ́n àwa ń ṣisẹ́ pọ̀ pẹ̀lú yín fún ayọ̀ yín nítorí nípa ìgbàgbọ́ ni ẹ̀yin dúró sinisin.

Ka pipe ipin 2 Kọ́ríńtì 1