Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2 Kọ́ríńtì 1:15-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Nítorí mo ní ìdánilójú yìí wí pé, mo pinnun láti kọ́kọ́ bẹ̀ yín wò kí ẹ lè jànfààní ìgbà méjì.

16. Mo pinnu láti bẹ̀ yín wò ní ìrìn àjò mi sí Makedóníà àti láti tún bẹ̀ yín wò nígbà tí mo bá ń padà bọ̀ láti Makedóníà àti wí pé kí ẹ̀yin kí ó lè rán mi láti ọ̀dọ̀ yín ní ìrìn àjò mi sí Jùdíà.

17. Nítorí náà nígbà tí èmi ń gbérò bẹ́ẹ̀, èmi há ṣiyèméjì bí? Tàbí àwọn ohun tí mo pinnu, mo ha pinnu wọn gẹ́gẹ́ bí ti ará bí, pé kí ó jẹ́ “Bẹ́ẹ̀ ní, bẹ́ẹ̀ ní” àti “Bẹ́ẹ̀ kọ́, bẹ́ẹ̀ kọ́”?

18. Ṣùgbọ́n bí Ọlọ́run tí jẹ́ olóòótọ́, ọ̀rọ̀ wa fún yín kí í ṣe bẹ́ẹ̀ ni ati bẹ́ẹ̀ kọ́.

19. Nítorí pé Jésù Kírísítì, Ọmọ Ọlọ́run, ẹni tí a tí wàásù rẹ̀ láàárin yín nípaṣẹ̀ èmí àti Silífánù àti Tímótíù, kì í ṣe bẹ́ẹ̀ ni bẹ́ẹ̀ kọ́, ṣùgbọ́n nínú rẹ̀ ni bẹ́ẹ̀ ní.

20. Nítorí tí gbogbo ìlérí Ọlọ́run dí bẹ́ẹ̀ ni nínú Kírísítì. Nítorí ìdí èyí ní a ṣe ń wí pé “Àmín” nípaṣẹ̀ rẹ̀ sí ògo Ọlọ́run.

21. Ǹjẹ́ níṣinṣin yìí, Ọlọ́run ni ó fí ẹsẹ̀ wa múlẹ̀ pẹ̀lú yín nínú Kírísítì, Òun ni ó ti fi àmì òróró yàn wá,

22. ó sì fí èdìdì rẹ̀ dì wá pẹ̀lú, ó sì tí fi Ẹ̀mí rẹ́ sí wa ní ọkàn gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí ìdánilójú ohun tí ó ń bọ̀.

23. Mo sì pe Ọlọ́run ṣe ẹlẹ́rìí ọkàn mi pé nítorí àtidá yín sí ní èmi kò ṣe padà sí Kọ́ríńtì.

24. Kì í ṣe nítorí tí àwa jẹ gàba lórí ìgbàgbọ́ yín: ṣùgbọ́n àwa ń ṣisẹ́ pọ̀ pẹ̀lú yín fún ayọ̀ yín nítorí nípa ìgbàgbọ́ ni ẹ̀yin dúró sinisin.

Ka pipe ipin 2 Kọ́ríńtì 1