Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Tímótíù 6:13-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. Mo paṣẹ fún ọ níwájú Ọlọ́run, tí ń sọ ohun gbogbo di ààyè, àti níwájú Jésù Kírísítì, ẹni tí ó jẹ́rìí níwájú Pọ́ńtíù Pílátù,

14. Kí ìwọ pa àṣẹ wọ̀nyí mọ́ ní àìlábàwọ́n, ní àìlẹ́gàn, títí di ìfarahàn Olúwa wa Jésù Kírísítì.

15. Èyí ti yóò fi hàn ní ìgbà tirẹ̀, Ẹni tí í ṣe Olùbùkún àti Alágbára kan ṣoṣo náà, Ọba àwọn ọba, àti Olúwa àwọn Olúwa.

16. Ẹnìkan ṣoṣo tí ó ní àìkú, tí ń gbé inú ìmọ́lẹ̀ tí a kò lè súnmọ́, ẹni tí ènìyàn kan kò rí rí tí a kò sì lè rí: ẹni tí ọlá àti agbára títí láé ń ṣe tirẹ̀ (Àmín).

17. Kìlọ̀ fún àwọn tí ó lọ́rọ̀ ní ayé ìṣinṣinyìí kí wọn ma ṣe gbéraga, bẹ́ẹ̀ ni kí wọn má ṣe gbẹ́kẹ̀lé ọ̀rọ̀ àìdánilójú, bí kò se lé Ọlọ́run alààyè, tí ń fi ohun gbogbo fún wa lọ́pọ̀lọpọ̀ láti lò;

18. Kí wọn máa ṣoore, kí wọn máa pọ̀ ní iṣẹ́ rere, kí wọn múra láti pín fúnni, kí wọn ni ẹ̀mí ìbákẹ́dùn;

19. Kí wọn máa to ìṣúra ìpìlẹ̀ rere jọ fún ara wọn dé ìgbà tí ń bọ̀, kí wọn lè di ìyè tòótọ́ mú.

20. Tìmótíù, máa sọ ohun tí a fi sí ìtọ́jú rẹ, yà kúrò nínú ọ̀rọ̀ asán àti ìjiyàn ohun tí a ń fi èké pè ni ìmọ̀;

21. Èyí tí àwọn ẹlòmíràn jẹ́wọ́ rẹ̀ tí wọ́n sì sìnà ìgbàgbọ́.Kí oore-ọ̀fẹ́ wà pẹ̀lú rẹ. Àmín.

Ka pipe ipin 1 Tímótíù 6