Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Tímótíù 5:19-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

19. Má ṣe gba ẹ̀sùn sí alàgbà kan, bí kò ṣe láti ẹnu ẹlẹ́rìí méjì-mẹ́ta.

20. Bá àwọn tí ó ṣẹ̀ wí níwájú gbogbo ènìyàn, kí àwọn ìyókù pẹ̀lú bà á lè bẹ̀rù.

21. Mo pàṣẹ fún ọ níwájú Ọlọ́run, àti Kírísítì Jésù, àti àwọn ańgẹ́lì àyànfẹ́ kí ìwọ máa ṣakíyèsí nǹkan wọ̀nyí, láìṣe ojúṣàájú, láti fi ègbè ṣe ohunkóhun.

22. Má ṣe fi ìkánjú gbe ọwọ́ lé ẹnikẹ́ni, bẹ́ẹ̀ ni kí ó má sì ṣe jẹ́ alábàápín nínú ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ẹlòmíràn: pa ara rẹ mọ́ ní ìwà funfun.

23. Ma ṣe máa mu omi nìkan, ṣùgbọ́n máa lo wáìnì díẹ̀ nítorí inú rẹ, àti nítorí àìlera ìgbàkúùgbà.

24. Ẹ̀sẹ̀ àwọn ẹlòmíràn a máa hàn gbangba, a máa lọ ṣáájú sí ìdájọ́; tí àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú a sì máa tẹ̀lé wọn.

25. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ pẹ̀lú ni iṣẹ́ rere wa máa ń hàn gbangba; bí wọn kò tilẹ̀ tíì hàn, wọn kò lè farasin títí.

Ka pipe ipin 1 Tímótíù 5