Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Tímótíù 3:2-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Ǹjẹ́ Bíṣọ́ọ̀bù yẹ kí ó jẹ́ aláìlẹ́gàn, ọkọ aya kan, olùsọ̀ràn, aláìrékọjá, oníwà yíyẹ, olùfẹ́ àlejò ṣíṣe, ẹni tí ó lè ṣe olùkọ́.

3. Kí ó má jẹ́ ọ̀mùtí, tàbí alu-ni, tàbí olójúkòkòrò, bí kò ṣe onísùúrù, kí ó má jẹ́ oníjà, tàbí olùfẹ́ owó.

4. Ẹni tí ó káwọ́ ilé ara rẹ̀ gírígírí, tí ó mú àwọn ọmọ rẹ̀ tẹríba pẹ̀lú ìwà àgbà gbogbo;

5. Ṣùgbọ́n bí ènìyàn kò bá mọ̀ bí a ti ń ṣe ìkáwọ́ ilé ara rẹ̀, òun ó há ti ṣe lè tọ́jú ìjọ Ọlọ́run?

6. Kí ó má jẹ́ ẹni titun ti ó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbàgbọ́, kí ó má baà gbéraga, a sì ṣubú sínú ẹ̀bi Èsù.

7. Ó sì yẹ kí ó ni ẹ̀rí rere pẹ̀lú lọ́dọ̀ àwọn tí ń bẹ lóde; kí ó má baà bọ́ sínú ẹ̀gàn àti sínú ìdẹ́kun Èṣù.

8. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ó yẹ fún àwọn Díákónì láti ní ìwà àgbà, kí wọ́n máa jẹ́ ẹlẹ́nu méjì, kí wọ́n máa fi ara wọn fún wáìnì púpọ̀, kí wọ́n má jẹ́ olójúkòkòrò.

Ka pipe ipin 1 Tímótíù 3