Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Tímótíù 3:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ náà, bí ẹnìkan bá fẹ́ ipò Bíṣọ́ọ̀bù, iṣẹ́ rere ni ó ń fẹ́,

2. Ǹjẹ́ Bíṣọ́ọ̀bù yẹ kí ó jẹ́ aláìlẹ́gàn, ọkọ aya kan, olùsọ̀ràn, aláìrékọjá, oníwà yíyẹ, olùfẹ́ àlejò ṣíṣe, ẹni tí ó lè ṣe olùkọ́.

3. Kí ó má jẹ́ ọ̀mùtí, tàbí alu-ni, tàbí olójúkòkòrò, bí kò ṣe onísùúrù, kí ó má jẹ́ oníjà, tàbí olùfẹ́ owó.

4. Ẹni tí ó káwọ́ ilé ara rẹ̀ gírígírí, tí ó mú àwọn ọmọ rẹ̀ tẹríba pẹ̀lú ìwà àgbà gbogbo;

5. Ṣùgbọ́n bí ènìyàn kò bá mọ̀ bí a ti ń ṣe ìkáwọ́ ilé ara rẹ̀, òun ó há ti ṣe lè tọ́jú ìjọ Ọlọ́run?

6. Kí ó má jẹ́ ẹni titun ti ó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbàgbọ́, kí ó má baà gbéraga, a sì ṣubú sínú ẹ̀bi Èsù.

7. Ó sì yẹ kí ó ni ẹ̀rí rere pẹ̀lú lọ́dọ̀ àwọn tí ń bẹ lóde; kí ó má baà bọ́ sínú ẹ̀gàn àti sínú ìdẹ́kun Èṣù.

8. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ó yẹ fún àwọn Díákónì láti ní ìwà àgbà, kí wọ́n máa jẹ́ ẹlẹ́nu méjì, kí wọ́n máa fi ara wọn fún wáìnì púpọ̀, kí wọ́n má jẹ́ olójúkòkòrò.

9. Kí wọn máa di ohun ìjìnlẹ̀ ìgbàgbọ́ mú pẹ̀lú ọkàn funfun.

10. Kí a kọ́kọ̀ wádìí àwọn wọ̀nyí dájú pẹ̀lú; nígbà náà ni kí a jẹ́ kí wọn ó ṣiṣẹ́ díákónì, bí wọn bá jẹ́ aláìlẹ́gàn.

Ka pipe ipin 1 Tímótíù 3