Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kọ́ríńtì 9:7-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Ta ni ó síṣẹ́ ogun nígbà tí ó sanwo ara rẹ̀? Ta ní gbin ọgbà àjàrà tí kì í jẹ nínú èso rẹ̀?, Tàbí ta ní ń bọ ọ̀wọ́-ẹran tí kì í sí ì jẹ nínú wàrà ọ̀wọ́-ẹran?

8. Èmi ha sọ nǹkan wọ̀nyí bí ènìyàn? Tàbí òfin kò wí bákan náà bì?

9. Nítorí nínú òfin tí Ọlọ́run fún Mósè, ni a tí kọ ọ́ pé, “Ìwọ kò gbọdọ̀ di màlúù ti ń pakà nínú oko rẹ̀ lẹ́nu mọ́.” Ǹjẹ́ màlúù ni Ọlọ́run n ṣe ìtọ́jú rẹ̀ bi?

10. Dájúdájú ó sọ eléyìí fún wa pé, nítorí wa ni a se kọ̀wé yìí kí ẹni tí ń tulẹ̀ lè máa tulẹ̀ ní ìrètí àti ẹni tí ń pakà lè ni ìretí láti ní ipin nínú ìkórè.

11. A ti fún irúgbìn èso ẹ̀mí sìnú ọkàn yín. Ẹ rò pé ó pọ̀jù fún wa tàbí ẹ kà á sí àṣejù, láti béèré fún oúnjẹ àti aṣọ fún àyọrísí iṣẹ́ wa bí?

12. Bí àwọn ẹlòmírán bá ní ẹ̀tọ́ tí ìrànlọ́wọ́ sì wá láti ọ̀dọ̀ yín, àwa ha kọ́ ni ó tọ́ sí jù?Ṣùgbọ́n àwa kò lo agbára yìí ṣùgbọ́n àwa faradà ohun gbogbo, kí àwa má baà ṣe ìdènà fún ìyìn rere Kírísítì.

13. Ǹjẹ́ ó yé e yín pé Ọlọ́run sọ fún àwọn tí ó ń siṣẹ́ nínú tẹ́ḿpìlì pé kí wọ́n mú oúnjẹ tàbí àwọn ẹ̀bùn tí wọ́n mú wá fún òun, làti fi se ìtọ́ju ara wọn? Àti àwọn tí ń dúró tí pẹpẹ wọn a máa se àjọpín pẹ̀lú pẹpẹ.

14. Lọ́nà kan náà ni Olúwa ti fi àṣẹ lélẹ̀ pé, àwọn tí ń wàásù íyìnrere kí wọn sì máa jẹ́ ní ti ìyìn rere.

15. Ṣíbẹ̀síbẹ̀ n kò ì tí ì lo iru àwọn ẹ̀tọ́ wọ̀nyí rí. Bẹ́ẹ̀ ni èmi kò sì kọ lẹ́tà yìí láti fi sọ fún un yín pé, mo fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í gbà irú nǹkan bẹ̀ẹ́ lọ́wọ́ yín. Kí a sọ òtítọ́, ó sàn fún mi láti kú sínú ebi ju pé kí n sọ ayọ̀ tí mo ní láti wàásù nù.

16. Nítorí pé bí mo ti ń wàásù ìyìn rere, kì í se ohun tí mo lè máa sogo lè. Èmi kò tilẹ̀ le è ṣe é ní, kí a tilẹ̀ sọ pé mo fẹ́ kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Ègbé ni fún mi tí mo bá kọ̀ láti wàásù ìyìn rere.

Ka pipe ipin 1 Kọ́ríńtì 9