Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kọ́ríńtì 7:19-34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

19. Ìkọlà kò jẹ́ nǹkan àti àìkọlà kò jẹ́ nǹkan, bí kò ṣe pípa òfin Ọlọ́run mọ́.

20. Ó yẹ kí ẹnìkọ̀ọ̀kan máa ṣe iṣẹ́ tí ó ń ṣe tẹ́lẹ̀, kí Ọlọ́run tó pé é sínú ìgbàgbọ́ nínú Kírísítì.

21. Ǹjẹ́ ẹrú ni ọ́ bí nígbà ti a pè ọ́? Má ṣe kà á sí. Ṣùgbọ́n tí ìwọ bá le di òmìnira, kúkú ṣe èyí nì.

22. Tí ó bá jẹ́ ẹrú, ti Olúwa sì pé ọ, rántí pé Kírísítì ti sọ ọ́ di òmìnira kúrò lọ́wọ́ agbára búburú ti ẹ̀ṣẹ̀. Tí ó bá sì ti pé ọ̀ nítòótọ́ tí ó sì ti di òmìnira, ó ti di ẹrú Kírísítì.

23. A sì ti rá yín ní iyè kan, nítorí náà ẹ má ṣe di ẹrú ènìyàn.

24. Ará, jẹ́ kí olúkúlùkù ènìyàn, nínú èyí tí a pè é, kí ó dúró nínú ọ̀kan náà pẹ̀lú Ọlọ́run.

25. Ṣùgbọ́n nípa ti àwọn wúndíá: èmi kò ní aṣẹ kankan láti ọ̀dọ̀ Olúwa, ṣùgbọ́n mo wí fún yín ní ìdájọ́ bí ẹni tí ó rí àánú Olúwa gbà láti jẹ́ olódodo.

26. Nítorí náà mo rò pé èyí dára nítorí wàhálà ìsinsinyìí, èyi nì ni pé o dára fún ènìyàn kí ó wà bí ẹ ṣe wà.

27. Ṣùgbọ́n tí ó bá ti gbéyàwó tàbí tí ó bá ti lákòókó, ẹ má ṣe kọ ara yín sílẹ̀, nítorí èyí tí mo wí yìí. Ṣùgbọ́n tí kò bá sì tí ì gbéyàwó, tàbí fẹ́ ọkọ, má ṣe sáre láti ṣe bẹ́ẹ̀ lákókó yìí.

28. Ṣùgbọ́n bí ìwọ bá gbé ìyàwó ìwọ kò dẹ́sẹ̀, bí a bá gbé wúndíá ní ìyàwó òun kò dẹ́sẹ̀. Ṣùgbọ́n irú àwọn tí ó bá gbé ìyàwó yóò dojú kọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ wàhálà nípa ti ara: ṣùgbọ́n mo dá a yín sí.

29. Òun ti mo ń wí ará, ni pé kúkúrú ni àkókò, láti ìsinsinyìí lọ, ẹni tí ó ni aya kí ó dàbí ẹni tí kò ní rí;

30. àwọn tí ń sọkún, bí ẹni pé wọn kò sọkún rí, àti àwọn tí ń yọ̀ bí ẹni pé wọn kò yọ̀ rí, àti àwọn tí ń rà bí ẹni pé wọn kò ní rí,

31. àti àwọn tó ń lo ohun ayé yìí, bí ẹni tí kò ṣe àṣejù nínú wọn: nítorí àṣà ayé yìí ń kọ́ja lọ.

32. Nínú gbogbo nǹkan tí ẹ bá ń ṣe ni mo tí fẹ́ kí ẹ sọ ara yín di òmìnira lọ́wọ́ àníyàn. Ọkùnrin tí kò ní ìyàwó le lo àkókò rẹ̀ láti fi siṣẹ́ fún Olúwa, yóò sì má ronú bí ó ti ṣe le tẹ́ Olúwa lọ́rùn.

33. Ṣùgbọ́n ọkùnrin tí ó bá tí ṣe ìgbéyàwó kò le ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí ó ní láti ronú àwọn ẹrù rẹ̀ nínú ayé yìí àti bí ó ti ṣe le tẹ́ aya rẹ̀ lọ́rùn,

34. dájúdájú, ìfẹ́ rẹ̀ pín sí ọ̀nà méjì. Bákan náà ló rí fún obìnrin tí ó bá wà nílé ọkọ, irú ìṣòro kan náà ni ó dojú kọ. Ọmọbìnrin tí kò bá tí ì délé ọkọ a máa ṣàkìtiyan láti tẹ́ Olúwa lọ́rùn ní gbogbo ìwà àti ìṣe àti ní tí ẹ̀mí. Ṣùgbọ́n ọmọbìnrin tí a bá ti gbé níyàwó, a máa ṣe àkíyèsí ohun púpọ̀, yóò máa wá ọ̀nà láti tẹ́ ọkọ rẹ̀ lọ́rùn.

Ka pipe ipin 1 Kọ́ríńtì 7