Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kọ́ríńtì 6:16-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. Tàbí ẹ kò mọ̀ pé bí ẹnìkan bá so ara rẹ̀ pọ̀ mọ́ àgbérè ó jẹ́ ara kan pẹ̀lú rẹ̀? Nítorí a tí kọ ọ́ wí pé, “Àwọn méjèèjì ni yóò di ara kan ṣoṣo.”

17. Ṣùgbọ́n ẹni ti ó dápọ̀ mọ́ Olúwa di ẹ̀mí kan náà pẹ̀lú rẹ̀.

18. Ẹ máa sá fún àgbérè. Gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí ènìyàn ń dá wà lóde ara, ṣùgbọ́n ẹni tí ń ṣe àgbérè ń ṣe sí ara òun tìká ara rẹ̀.

19. Tàbí, ẹ̀yin kò mọ̀ pé ara yín ni tẹ́ḿpìlì Ẹ̀mí Mímọ́, ti ń bẹ nínú yín, ti ẹ̀yin ti gbà lọ́wọ́ Ọlọ́run? Ẹ̀yin kì í ṣe ti ara yín,

20. nítorí a ti rà yín ni iye kan; Nítorí náà ẹ yìn Ọlọ́run lógo nínú ara yín, àti nínú ẹ̀mí yín, tì í ṣe ti Ọlọ́run.

Ka pipe ipin 1 Kọ́ríńtì 6