Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kọ́ríńtì 3:16-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. Ṣé ẹ̀yin kò tilẹ̀ mọ̀ pé tẹ́ḿpìlì Ọlọ́run ni ẹ̀yin jẹ́? Pé Ẹ̀mí Ọlọ́run ń gbé inú yín?

17. Bí ẹnikẹ́ni bá ba tẹ́ḿpìlì Ọlọ́run jẹ́, òun ni Ọlọ́run yóò parun; nítorí pé mímọ́ ni tẹ́ḿpìlì Ọlọ́run, èyí tí ẹ̀yín jẹ́.

18. Kí ẹnikẹ́ni, má ṣe tan ara rẹ̀ jẹ mọ́. Bí ẹnikẹ́ni yín nínú ayé yìí ba rò pé òun gbọ́n, ẹ jẹ́ kí ó di òmùgọ̀ kí ó bá a le è gbọ́n.

19. Nítorí ọgbọ́n ayé yìí jẹ́ òmùgọ lọ́dọ̀ Ọlọ́run. Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ nínú ìwé Mímọ́ pé, “Ẹni ti tí ó mu àwọ̀n ọlọgbọ́n nínú àrékerèke wọn.”

20. lẹ́ẹ̀kan síi, “Olúwa mọ̀ èrò inú àwọn ọlọ́gbọ́n pé, asán ní wọn.”

21. Nítorí kí ẹnikẹ́ni má ṣe ṣògo nínú ènìyàn. Nítorí tí yín ni ohun gbogbo.

22. Ìbá ṣe Pọ́ọ̀lù, tàbí Àpólò, tàbí Kéfà, tàbí ayé tàbí ìyè, tàbí ikú, tàbí ohun ìsinsinyìí, tàbí ohun ìgbà tí ń bọ̀; ti yín ni gbogbo wọn.

23. Ẹ̀yin sì ni ti Kírísítì; Kírísítì sì ni ti Ọlọ́run.

Ka pipe ipin 1 Kọ́ríńtì 3