Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kọ́ríńtì 15:41-48 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

41. Ọ̀tọ̀ ni ògo ti òòrùn, ọ̀tọ̀ ni ògo ti òṣùpá, ọ̀tọ̀ sì ni ògo ti ìràwọ̀; ìràwọ̀ sá yàtọ̀ sí ìràwọ̀ ni ògo.

42. Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ sí ni àjíǹde òkú. A gbìn ín ní ìdibàjẹ́; a sí jì í didé ni àìdíbàjẹ́:

43. A gbìn ín ni àìní ọlá, a sí jí i dìde ni ògo; a gbìn ín ni àìlera, a sì ji í dìde ní agbára.

44. A gbìn ín ni ara ti ọkàn, a sì jí i dìde ni ara ti ẹ̀mí.Bí ara tí ọkàn bá ń bẹ, ara ẹ̀mí náà sì ń bẹ.

45. Bẹ́ẹ̀ ní a si kọ ọ́ pé, “Ádámù ọkùnrin ìṣáàjú, alààyè ọkàn ni a dá a” Ádámù ìkẹ́yìn ẹ̀mí ti ń fún ní ní ìyè.

46. Ṣùgbọ́n èyí tí í ṣe tí ẹ̀mí kọ ní ó kọ́kọ́ ṣáajú, bí kò ṣe èyí tí í ṣe tí ọkàn, lẹ́yìn náà èyí ti í ṣe ti ẹ̀mí.

47. Ọkùnrin ìṣáájú ti inú erùpẹ̀ wá, ẹni erùpẹ̀: ọkùnrin èkejì láti ọ̀run wá ni.

48. Bí ẹni erùpẹ̀ ti rí, irú bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn tí í ṣe erùpẹ̀: bí ẹni tí ọ̀run ti rí, irú bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn tí í ṣe tí ọ̀run.

Ka pipe ipin 1 Kọ́ríńtì 15