Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kọ́ríńtì 15:32-36 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

32. Kí a wí bí ènìyàn, bí mo bá ẹranko jà ní Éfésù, àǹfàání kín ni ó jẹ́ fún mi? Bí àwọn òkú kò bá jínde,“Ẹ jẹ́ kí a máa jẹ kí á máa mú;nítorí ní ọlá ni àwa ó kú.”

33. Kí a má tàn yín jẹ́: “Ẹgbẹ́ búburú bá ìwà rere jẹ́!?”

34. Ẹ ji ìjí òdodo, kí ẹ má sì dẹ́ṣẹ̀; nítorí àwọn ẹlómírán kò ni imọ̀ Ọlọ́run: mo sọ èyí kí ojú baà lè ti yín.

35. Ṣùgbọ́n ẹnìkan yóò wí pé, “Báwo ni àwọn òkú yóò ṣe jíǹde? Irú ara wó ni wọn ó padà sí?”

36. Iwọ aláìmòye, ohun tí ìwọ fúnrúgbìn kì í yè bí kò ṣe pé ó kú:

Ka pipe ipin 1 Kọ́ríńtì 15