Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kọ́ríńtì 15:22-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

22. Nítorí bí gbogbo ènìyàn ti kú nínú Ádámù, bẹ́ẹ̀ ní a ó sì sọ gbogbo ènìyàn dí alààyè nínú Kírísitì.

23. Ṣùgbọ́n olúkúlùkù ènìyàn ní ipá tirẹ̀: Kírísítì àkọ́bí; lẹ́yin èyí àwọn tí ó jẹ́ tí Kírísítì ni wíwá rẹ̀.

24. Nígbá náà ni òpín yóò dé, nígbà tí ó bá ti fi ìjọba fún Ọlọ́run Baba, nígbà tí ó bá pá gbogbo àṣẹ àti gbogbo ọlá àti agbára run.

25. Nítorí ti òun gbọdọ̀ ti jọba kí òun to fí gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ sí abẹ́ ẹṣẹ̀ rẹ̀.

26. Ikú ní ọ̀ta ìkẹ́yìn tí a ó párun

27. “Nítorí ó ti fí ohun gbogbo sábẹ́ ẹṣẹ̀ rẹ̀.” Ṣùgbọ́n nígbà tí ó wí pé, “Ohun gbogbo ni á fí sí abẹ́ rẹ̀,” o dájú pé Ọlọ́run nìkanṣoṣo ní kò sí ní abẹ́ rẹ̀, Òun ní ó fí ohun gbogbo sí abẹ́ àkóso Kírísítì.

28. Nígbà tí a bá sì fi ohun gbogbo sí abẹ́ rẹ̀ tán, nígbà náà ni á ó fi ọmọ tìkárarẹ̀ pẹ̀lú sábẹ́ Ẹni tí ó fí ohun gbogbo sí abẹ́ rẹ̀, kí Ọlọ́run lè jásí ohun gbogbo nínú ohun gbogbo.

29. Ní báyìí, bí kò bá sí àjíǹde, kín ní ète àwọn ènìyàn tí wọn ń tẹ bọmi nítorí òkú? Bí àwọn òkú kò bá jíǹde rárá, nítorí kín ni a ṣe ń bamítíìsì wọn nítorí wọn?

Ka pipe ipin 1 Kọ́ríńtì 15