14. Bí Kírísítì kò bá sì jíǹde, ǹjẹ́ asán ni ìwàásù wà, asán sì ni ìgbàgbọ́ yín pẹ̀lú.
15. Ṣùgbọ́n jù bẹ́ẹ̀ lọ, a mú wa ni ẹlẹ́rìí èké fún Ọlọ́run; nítorí ti àwa jẹ́rìí Ọlọ́run pé ó jí Kírísítì dìdé kúrò nínú òkú: ẹni tí òun kò jí dìde bí ó bá ṣe pé àwọn òkú kò jíǹde?
16. Nítorí pé bi á kò bá jí àwọn òkú dìde, ǹjẹ́ a kò jí Kírísítì dìdé,
17. Bí a kò bá sì jí Kírísítì dìdé, asán ní ìgbàgbọ́ yín; ẹ̀yín wà nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín síbẹ̀.
18. Ǹjẹ́ àwọn pẹ̀lú tí ó sùn nínú Kírísítì ṣègbé.
19. Bí ó bá ṣe pé kìkì ayé yìí nìkan ní àwa ní ìrétí nínú Kírísítì, àwa jásí òtòsì jùlọ nínú gbogbo ènìyàn.
20. Ǹjẹ́ nísinsìnyìí Kírísítì tí jíǹde kúró nínú òkú, ó sì dí àkọ́bí nínú àwọn tí ó sùn.
21. Nítorí ìgbà tí ó jẹ́ pé nípa ènìyàn ní ikú ti wá, nipá ènìyàn ní àjíǹde òkú sì ti wá pẹ̀lú.
22. Nítorí bí gbogbo ènìyàn ti kú nínú Ádámù, bẹ́ẹ̀ ní a ó sì sọ gbogbo ènìyàn dí alààyè nínú Kírísitì.
23. Ṣùgbọ́n olúkúlùkù ènìyàn ní ipá tirẹ̀: Kírísítì àkọ́bí; lẹ́yin èyí àwọn tí ó jẹ́ tí Kírísítì ni wíwá rẹ̀.