Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kọ́ríńtì 15:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ǹjẹ́ ará, èmi ń sọ ìyinrere náà dí mímọ̀ fún un yín, tí mo ti wàásù fún un yín, èyí tí ẹ̀yin pẹ̀lú ti gbá, nínú èyí tí ẹ̀yin sì dúró.

2. Nípaṣẹ̀ ìyìn rere yìí ni a fi ń gbà yín là pẹ̀lú, bí ẹ̀yin bá di ọ̀rọ̀ ti mo ti wàásù fún yín mú ṣinṣin. Bí bẹ́ẹ̀ kọ̀, ẹyin kàn gbàgbọ́ lásán.

3. Nítorí èyí tí mo rí gbà ṣáájú ohun gbogbo ní èmi pẹ̀lú ti gbà lé e yín lọ́wọ́, bí Kírísítì ti kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wá gẹ́gẹ́ bí ìwé mímọ́ tí wí.

4. Àti pé a sìnkú rẹ̀, àti pé ó jíǹdé ní ijọ́ kẹtà gẹ́gẹ́ bí iwe mímọ́ tí wí;

5. Àti pé ó farahàn Pétérù, lẹ́yìn èyí, àwọn méjìlá

6. Lẹ́yìn èyí, ó farahàn àwọn ará tí o jú ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀tà lọ lẹ́ẹ̀kan náà; ọ̀pọ̀ nínú wọn wà títí fí di ìsinsìnyìí, ṣùgbọ́n àwọn díẹ̀ ti sùn.

7. Lẹ́yìn èyí ni ó farahan Jèmísì; lẹ́yìn náà fún gbogbo àwọn Àpósítélì.

8. Àti níkẹyín gbogbo wọn ó fáráhàn mí pẹ̀lú, bí ẹni tí a bí ṣáájú àkókò rẹ̀.

Ka pipe ipin 1 Kọ́ríńtì 15