Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Kọ́ríńtì 12:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ní ti Ẹ̀mí Mímọ́ ẹ̀yin ará, kò yẹ́ kí ẹ jẹ́ òpè.

2. Ẹ̀yin kò mọ̀ pé nígbà tí ẹ̀yin jẹ́ abọ̀rìṣà, a fà yín lọ sọ́dọ̀ odi òrìṣà, ni ọ̀nà tí ó wù kí a gbà fà yín lọ.

3. Nítorí náà, èmí ń sọ fún un yín pé kò sí ẹni ti ń sọ̀rọ̀ nípaṣẹ̀ Ẹ̀mí Ọlọ́run tí ó lè wí pé, “Ẹni ìfibú ni Jésù,” àti pé kò sí ẹni tí ó lè sọ pé, “Olúwa ni Jésù,” bí kò ṣe nípàṣẹ̀ Ẹ̀mí mímọ́.

4. Ǹjẹ́ onírúurú ẹ̀bùn ni ó wà, ùgbọ́n Ẹ̀mí kan náà ni.

Ka pipe ipin 1 Kọ́ríńtì 12