Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Jòhánù 3:5-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Ẹ̀yin sì mọ̀ pé, òun farahàn láti mu ẹ̀ṣẹ̀ kúrò; ẹ̀ṣẹ̀ kò sì sí nínú rẹ̀.

6. Ẹnikẹ́ni tí o ba ń gbé inú rẹ̀ kì í dẹ́ṣẹ̀; ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ń dẹ́ṣẹ̀ kò rí i, bẹ́ẹ̀ ni kò mọ̀ ọ́n.

7. Ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tàn yín: ẹni tí ó bá ń ṣe òdodo, ó jásí olódodo, gẹ́gẹ́ bí òun tí jẹ olódodo.

8. Ẹni tí ó ba ń dẹ́ṣẹ̀ tí èṣù ni; nítorí láti àtètèkọ́ṣe ni Èṣù ti ń dẹ́ṣẹ́. Nítorí èyí ni Ọmọ Ọlọ́run ṣe farahàn, kí o lè pa iṣẹ́ Èṣù run.

9. Ẹnikẹ́ni tí a ti ipa Ọlọ́run bí, kì í dẹ́ṣẹ̀; nítorí tí irú rẹ̀ ń gbé inú rẹ̀: kò sì lè dẹ́ṣẹ̀ nítorí pé a ti ti ipa Ọlọ́run bí i.

10. Nínú èyí ni àwọn ọmọ Ọlọ́run ń farahàn, àti àwọn ọmọ Èṣù; ẹníkẹni í kò ba ń ṣe òdodo, àti ẹni tí kò fẹ́ràn arákùnrin rẹ̀ kì í ṣe ti Ọlọ́run.

11. Nítorí èyí ni iṣẹ́ tí ẹ̀yin tí gbọ́ ni àtètèkọ́ṣe, pé ki àwa fẹ́ràn ara wa.

12. Kì í ṣe bí Káínì, tí í ṣe ẹni búburú, tí o sì pa arákùnrin rẹ̀. Nítorí kín ni ó sì ṣe pa á? Nítorí tí iṣẹ́ tirẹ̀ jẹ́ búburú ṣùgbọ́n tí arakúnrin rẹ̀ sì jẹ́ òdodo.

13. Kì ẹnu má ṣe yà yín, ẹ̀yin ará mi, bí ayé bá kóríra yín.

14. Àwa mọ̀ pé àwa tí rékọjá láti inú ikú sínú ìyè, nítorí tí àwa fẹ́ràn àwọn ará. Ẹni tí kò ba ni ìfẹ́ ó ń gbé inú ikú.

15. Ẹnikẹ́ni tí ó ba kórìíra arákùnrin rẹ̀ apànìyàn ni: ẹ̀yin sì mọ́ pé kò sí apànìyàn tí o ni ìyè àìnípẹ̀kun láti máa gbé inú rẹ̀.

Ka pipe ipin 1 Jòhánù 3