Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Jòhánù 3:11-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Nítorí èyí ni iṣẹ́ tí ẹ̀yin tí gbọ́ ni àtètèkọ́ṣe, pé ki àwa fẹ́ràn ara wa.

12. Kì í ṣe bí Káínì, tí í ṣe ẹni búburú, tí o sì pa arákùnrin rẹ̀. Nítorí kín ni ó sì ṣe pa á? Nítorí tí iṣẹ́ tirẹ̀ jẹ́ búburú ṣùgbọ́n tí arakúnrin rẹ̀ sì jẹ́ òdodo.

13. Kì ẹnu má ṣe yà yín, ẹ̀yin ará mi, bí ayé bá kóríra yín.

14. Àwa mọ̀ pé àwa tí rékọjá láti inú ikú sínú ìyè, nítorí tí àwa fẹ́ràn àwọn ará. Ẹni tí kò ba ni ìfẹ́ ó ń gbé inú ikú.

15. Ẹnikẹ́ni tí ó ba kórìíra arákùnrin rẹ̀ apànìyàn ni: ẹ̀yin sì mọ́ pé kò sí apànìyàn tí o ni ìyè àìnípẹ̀kun láti máa gbé inú rẹ̀.

16. Nípa èyí ni àwa mọ ìfẹ́ nítorí tí ó fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ fún wa: ó sì yẹ kí àwa fi ẹ̀mí wa lélẹ̀ fún àwọn ará.

17. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ni ohun ìní ayé, tí ó sì ri arákùnrin rẹ̀ tí ó ṣe aláìní, tí ó sì sé ìlẹ̀kùn ìyọ́nú rẹ̀ mọ́ ọn, báwo ni ìfẹ́ Ọlọ́run ṣe ń gbé inú rẹ̀?

18. Ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ má ṣe jẹ́ kí a fi ọ̀rọ̀ tàbí ahọ́n fẹ́ràn, bí kò ṣe ni ìṣe àti ní òtítọ́.

19. Àti nípa èyí ni àwa ó mọ̀ pé àwa jẹ́ ti òtítọ́, àti pé àwa ó sì dá ara wa lójú níwájú rẹ̀.

Ka pipe ipin 1 Jòhánù 3