Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Jòhánù 2:16-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. Nítorí ohun gbogbo tí ń bẹ nínú ayé: ìfẹ́kùfẹ́ ẹni ẹ̀sẹ̀, ìfẹ́kùfẹ́ ti ojú, àti ìgbéraga ti ohun ti ó ní àti ohun tí ó se: kò wá láti ọ̀dọ̀ Baba bí kò ṣe láti ọwọ́ ayé.

17. Ayé sì ń kọjá lọ àti ìfẹ́kùfẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó ba ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò wà títí láéláé.

18. Ẹ̀yin ọmọ mi ọ̀wọ́n, ìgbà ìkẹyìn ni èyí; bí ẹ̀yin sì tí gbọ́ pé Aṣòdìsí-Kírísítì ń bọ̀ wá, àní nísìnsin yìí, púpọ̀ Aṣòdì-sí-Kírísítì ló ń bẹ. Nípa èyí ni àwa fí mọ́ pé ìgbà ìkẹ́yìn ni èyí.

19. Wọn ti ọ̀dọ̀ wá jáde, ṣùgbọ́n wọn kì í ṣe ara wa. Nítorí bí wọ́n bá jẹ́ ara wa, wọn ìbá bá wa dúró: ṣùgbọ́n jíjáde lọ wọn fihàn pé gbogbo wọn kì í ṣe ara wa.

20. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ní ìfòróró-yàn láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí-mímọ́ wá, gbogbo yín sì mọ òtítọ́.

21. Èmi kò kọ̀wé sí yín nítorí pé ẹ̀yin kò mọ òtítọ́, ṣùgbọ́n nítorí tí ẹ̀yin mọ̀ ọ́n, àti pé kò sí èké nínú òtítọ́.

22. Ta ni èké? Ẹni tí ó sẹ́ pé Jésù kì í ṣe Kírísítì. Eléyìí ni Aṣòdìsí-Kírísítì: ẹni tí ó sẹ́ Baba àti Ọmọ.

23. Ẹnikẹ́ni tí o ba sẹ́ Ọmọ, kò gba Baba; ṣùgbọ́n ẹni tí o ba jẹ́wọ́ Ọmọ, ó gba Baba pẹ̀lú.

24. Ẹ jẹ́ kí èyí tí ẹ tí gbọ́ ni àtètèkọ́ṣe máa gbé inú yín. Bí èyí tí ẹ̀yin tí gbọ́ ní àtètèkọ́ṣe bá ń gbé inú yín, ẹ̀yin ó sì dúró nínú Ọmọ àti nínú Baba.

Ka pipe ipin 1 Jòhánù 2