Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sekaráyà 9:15-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò dáàbò bò wọ́n;wọn ó sì jẹ ni run,wọn ó sì tẹ òkúta kànnà-kànnà mọ́lẹ̀;wọn ó sì mu ẹ̀jẹ̀ wọn bí wáìnì,wọn ó sì kún bí ọpọ́n,wọn ó sì rin ṣinṣin bí àwọn igun pẹpẹ.

16. Olúwa Ọlọ́run wọn yóò sì gbà wọ́n là ni ọjọ́ náàbí agbo ènìyàn rẹ̀:nítorí wọn ó dàbí àwọn òkúta adé,tí a gbé sókè bí àmì lórí ilẹ̀ rẹ̀.

17. Nítorí oore rẹ̀ tí tóbi tó, ẹwà rẹ̀ ṣi tí pọ̀!Ọkà yóò mú ọ̀dọ́mọkùnrin dárayá,ati ọtí-wáìnì tuntun yóò mú àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú.

Ka pipe ipin Sekaráyà 9