Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sekaráyà 6:8-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Nígbà náà ni ohùn kan sì ké sí mi, ó sì bá mi sọ̀rọ̀ wí pé, “Wò ó, àwọn wọ̀nyí tí ó lọ síhà ilẹ̀ àríwá ti mú ẹ̀mí mi parọ́rọ́ ni ilẹ̀ àríwá.”

9. Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ mí wá, wí pé:

10. “Mú nínú ìgbèkùn, nínú àwọn Hélídáì, tí Tóbíyà, àti ti Jédáyà, tí ó ti Bábílónì dé, kí ìwọ sì wá ní ọjọ́ kan náà, kí o sì wọ ilé Jósáyà ọmọ Séfánáyà lọ.

11. Kí o sì mú sílifà àti wúrà, kí o sì fi ṣe adé púpọ̀, sì gbé wọn ka orí Jóṣúà ọmọ Jósédékì, olórí àlùfáà.

Ka pipe ipin Sekaráyà 6