Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sekaráyà 6:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Mo sì yípadà, mo sì gbé ojú mi sòkè, mo sì wò, sì kíyèsi i, kẹ̀kẹ́ mẹ́rin jáde wá láti àárin òkè-ńlá méjì, àwọn òkè-ńlà náà sì jẹ́ òkè-ńlà idẹ.

2. Àwọn ẹṣin pupa wà ní kẹ̀kẹ́ èkínní; àti àwọn ẹṣin dúdú ní kẹ̀kẹ́ èkejì.

3. Àti àwọn ẹṣin funfun ní kẹ̀kẹ́ ẹ̀kẹta; àti àwọn adíkálà àti alágbára ẹṣin ní kẹ̀kẹ́ ẹ̀kẹrin.

4. Mo sì dáhùn, mo sì béèrè lọ́wọ́ ańgẹ́lì tí ń bá mi sọ̀rọ̀ pé, “Kí ni ìwọ̀nyí, Olúwa mi.”

5. Ańgẹ́lì náà si dáhùn ó sì wí fún mi pé, “Wọ̀nyí ni àwọn ẹ̀mí mẹ́rin ti ọ̀run, tí wọn ń lọ kúrò lẹ́yìn tí wọ́n ti fi ara wọn hàn níwájú Olúwa gbogbo ayé.

6. Àwọn ẹṣin dúdú tí ó wà nínú rẹ̀ jáde lọ sí ilẹ̀ àríwá; àwọn funfun sì jáde tẹ̀lé wọn; àwọn adíkálà sì jáde lọ sí ìhà ilẹ̀ gúsù.”

7. Àwọn alágbára ẹṣin sì jáde lọ, wọ́n sì ń wá ọ̀nà àti lọ kí wọn báa lè rìn síhín-sọ́hùnún ni ayé; ó sì wí pé, “Ẹ lọ, ẹ lọ rìn síhìn-sọ́hùn ní ayé!” Wọ́n sì rín síhìnín-sọ́hùnún ní ayé.

Ka pipe ipin Sekaráyà 6