Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sekaráyà 11:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ṣí àwọn ìlẹ̀kùn rẹ sílẹ̀, ìwọ Lébánónì,kí iná bá lè jẹ igi Kédárì rẹ run,

2. Pohùnréré-ẹkún, igi fírì;nítorí igi Kédárì ṣubú,nítorí tí a ba àwọn igi tí o lógo jẹ́:ṣunkún kíkorò ẹ̀yin igi óákù tí Básánì,nítorí gé igbó àjàrà lulẹ̀.

3. Gbọ́ ohun igbe àwọn olùṣọ́-àgùntàn;ògo wọn bàjẹ́;gbọ́ ohùn bíbú àwọn ọmọ kìnnìúnnítorí ògo Jódánì bàjẹ́.

4. Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run mi wí: “Bọ́ ọ̀wọ́-ẹran àbọ́pa.

5. Tí àwọn olúwa wọn ń pa wọ́n, tí wọn kò sì ka ara wọn sí pé wọn jẹ̀bi: àti àwọn tí ń tà wọ́n wí pé, ‘Ìbùkún ni fún Olúwa, nítorí tí mo dí ọlọ́rọ̀!’ Àwọn olùṣọ́ àgùntàn wọn kò sì ṣàánú wọn.

6. Nítorí èmi kì yóò ṣàánú fún àwọn ara ilẹ̀ náà mọ́,” ni Olúwa wí, “Ṣí kíyèsí í, èmi yóò fi olúkúlúkù ènìyàn lé aládùúgbò rẹ̀ lọ́wọ́, àti lé ọwọ́ ọba rẹ̀, wọn yóò sì fọ́ ilẹ̀ náà, èmi kì yóò sì gbà wọ́n lọ́wọ́ wọn.”

7. Èmi yóò sì bọ́ ẹran àbọ́pa, àní ẹ̀yin òtòsì nínú ọ̀wọ́ ẹran. Mo sì mu ọ̀pá méjì ṣọ́dọ̀; mo pè ọ̀kan ni Oore-ọ̀fẹ́, mo pè èkejì ni Àmùrè; mo sì bọ́ ọ̀wọ́-ẹran náa.

8. Olùṣọ àgùntàn mẹ́ta ni mo sì gé kúrò ní oṣù kan;Ọkàn mi sì kòrìíra wọn, ọkàn wọn pẹ̀lú sì kóríra mi.

9. Mo sì wí pé, “Èmi kì yóò bọ́ yin: èyí ti ń ku lọ, jẹ́ kí òkú o kú; èyí tí a o ba sì gé kúrò, jẹ́ kí a gé e kúrò; ki olúkúlùkù nínú àwọn ìyókù jẹ́ ẹran-ara ẹnìkejì rẹ̀.”

Ka pipe ipin Sekaráyà 11