Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sekaráyà 1:14-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Ańgẹ́lì ti ń bá mi sọ̀rọ̀ sì wí fún mi pé, “Ìwọ kígbé wí pé: Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: ‘Èmi ń fi ìjowú ńlá jówú fún Jérúsálẹ́mù àti fún Síónì.

15. Èmi sì bínú púpọ̀púpọ̀ si àwọn orílẹ̀-èdè tí o gbé jẹ́ẹ: nítorí nígbà ti mo bínú díẹ̀, wọ́n ran ìparun lọ́wọ́ láti tẹ̀ṣíwájú.’

16. “Nítorí náà, báyìí ni Olúwa wí: ‘Mo padà tọ Jérúsálẹ́mù wá pẹ̀lú àánú; ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, a ó kọ́ ilé mi sínú rẹ̀, a o sí ta okùn ìwọ̀n kan jáde sórí Jérúsálẹ́mù.’

17. “Má a ké síbẹ̀ pé: Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: ‘A o máa fi ire kun ilú-ńlà mi ṣíbẹ̀; Olúwa yóò sì máa tu Síónì nínú ṣíbẹ̀, yóò sì yan Jérúsálẹ́mù ṣíbẹ̀.’ ”

18. Mo si gbé oju sòkè, mo sì rí, sì kíyèsí i, ìwo mẹ́rin.

19. Mo sì sọ fún ańgẹ́lì tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀ pé, “Kí ni nǹkan wọ̀nyí?”Ó si dà mí lóhùn pé, “Àwọn ìwo wọ̀nyí ni ó tí tú Júdà, Ísírélì, àti Jérúsálẹ́mù ká.”

20. Olúwa sì fi alágbẹ̀dẹ mẹ́rin kan hàn mí.

21. Nígbà náà ni mo wí pé, “Kí ni àwọn wọ̀nyí wá ṣe?”O sì sọ wí pé, “Àwọn wọ̀nyí ni ìwo tí ó ti tú Júdà ká, tóbẹ́ẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò fi gbé orí rẹ̀ sòkè? Ṣùgbọ́n àwọn wọ̀nyí wá láti dẹ́rùbà wọ́n, láti lé ìwo àwọn orilẹ̀-èdè jáde, ti wọ́n gbé ìwo wọn sorí ilẹ̀ Júdà láti tú enìyàn rẹ̀ ká.”

Ka pipe ipin Sekaráyà 1