Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 99:5-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Gbígbé ga ní Olúwa Ọlọ́run waẹ foríbalẹ̀ níbi ẹṣẹ̀ Rẹ̀; ó jẹ́ mímọ́.

6. Mósè àti Árónì wà nínú àwọn àlùfáà Rẹ̀Sámúẹ́lì wà nínú àwọn tí ó ń ké pe orúkọ Rẹ̀wọ́n képe Olúwa, ó sì dá wọn lóhùn.

7. Ó sọ̀rọ̀ sí wọn nínú ọ̀wọ́n àwọsánmọ̀,wọ́n pa ẹrí Rẹ̀ mọ́ àti ìlànà tí ó fún wọn.

8. Olúwa Ọlọ́run wa, ó dá wọn lóhùn;ó jẹ́ Ọlọ́run tí ó ń dáríjìn àwọn ọmọ Ísírẹ́lììwọ tí ó ń fi ìyà àìṣedédé wọn jẹ wọ́n

9. Gbígbé ga ni Olúwa Ọlọ́run wakí a sìn ín ní òkè mímọ́ Rẹ̀nítorí Olúwa Ọlọ́run wa jẹ́ mímọ́.

Ka pipe ipin Sáàmù 99