Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 98:2-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Olúwa ti sọ ìgbàlà Rẹ̀ di mímọ̀o fí òdodo Rẹ̀ han àwọn orílẹ̀ èdè.

3. Ó rántí ìfẹ́ Rẹ̀ àti òtítọ́ Rẹ̀ fún àwọn ará ilé Ísírẹ́lì;gbogbo òpin ayé ni ó ti ríiṣẹ́ ìgbàlà Ọlọ́run wa.

4. Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Olúwa, gbogbo ayé,ẹ bu sáyọ̀, ẹ kọrin ìyìn

5. Ẹ fi dùùrù kọrin sí Olúwa, pẹ̀lú dùùrù àti ìró ohùn orin mímọ́,

6. Pẹ̀lú ìpè àti fèrèẹ hó fún ayọ̀ níwájú Olúwa Ọba.

7. Jẹ́ kí òkun kí o hó pẹ̀lú gbogboohun tí ó wà nínú Rẹ̀,Gbogbo ayé àti gbogbo àwọn tí ń gbé inú Rẹ̀.

8. Ẹ jẹ́ kí odo kí ó sápẹ́,ẹ jẹ́ kí òkè kí o kọrin pẹ̀lú ayọ̀;

9. Ẹ jẹ́ kí wọn kọrin níwájú OlúwaNítorí tí yóò wá ṣè dájọ́ ayébẹ́ẹ̀ ni yóò ṣe ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè nínú òdodoàti àwọn ènìyàn ní àìṣègbè pẹ̀lú.

Ka pipe ipin Sáàmù 98