Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 98:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ẹ kọrin túntún sí Olúwa,nítorí tí ó ṣe ohun ìyanu;ọwọ́ ọ̀tún Rẹ̀ àti apa mímọ́ Rẹ̀o ṣe iṣẹ́ ìgbàlà fún un

2. Olúwa ti sọ ìgbàlà Rẹ̀ di mímọ̀o fí òdodo Rẹ̀ han àwọn orílẹ̀ èdè.

3. Ó rántí ìfẹ́ Rẹ̀ àti òtítọ́ Rẹ̀ fún àwọn ará ilé Ísírẹ́lì;gbogbo òpin ayé ni ó ti ríiṣẹ́ ìgbàlà Ọlọ́run wa.

4. Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Olúwa, gbogbo ayé,ẹ bu sáyọ̀, ẹ kọrin ìyìn

5. Ẹ fi dùùrù kọrin sí Olúwa, pẹ̀lú dùùrù àti ìró ohùn orin mímọ́,

6. Pẹ̀lú ìpè àti fèrèẹ hó fún ayọ̀ níwájú Olúwa Ọba.

Ka pipe ipin Sáàmù 98